Home » Ta ló tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù?

Ta ló tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù?

0
IMG-20210607-WA0011.jpg

Láti ọwọ Mutiu Ọláwuyì

Tó bá ń fọùn dùndún lẹ́nu
Sùgbọ́n tóun àti àwọn ẹhànnà ń jẹ tí wọ́n ń mu,
Ó tọ́ sí ìgbájú Màkàrọ́nù
Àti iko lórí rẹ kodoro…

Tó bá ń se gààrù to kọtí ikún
Sí àwọn abẹ̀mi tó ń gbóríyìn fun,
Ó tọ́ sí ìgbájú Màkàrọ́nù
Àti iko lórí rẹ kodoro…

Tí àwọn abẹ̀mi tí ń bẹ lábẹ́ àbò rẹ
Bá dégbò tí wọ́n ya lára fẹ́rẹfẹ̀rẹ,
Ọ tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àti iko lórí rẹ kodoro…

Tí wọ́n bá rò pé àwọn ló ṣe pàtàkì jùlọ
Tí wọ́n ò tún mọ̀ ju ká fọlá láni lójú lọ,
Wọ́n tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí wọn kodoro…

Tí wọ́n bá sebí adití ati ọyaya
Láti sètẹnimẹ́rẹ̀ pẹ̀lú abúgbàmù àtọta,
Wọ́n tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí wọn kodoro…

Tí wọ́n bá kó aìrójú-aìráyé
Bá àwọn àwùjọ inú ayé,
Wọ́n tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí wọn kodoro…

Tí wọ́n bá kọwọ́ bojú ara
Àwọn alápòlánínú láìbìkítà rárá,
Wọ́n tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí wọn kodoro…

Tí wọ́n bá ń yọ̀ tẹ̀rẹ̀ káàkiri ayé
Bí àwọn òkú inú àyéè,
Wọ́n tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí wọn kodoro…

Tó bà tọ́ ọmọ rẹ dáradára
Tó fi ya àbíìpábẹ́ ọmọ rádaràda,
Ọ tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí rẹ kodoro…

Tó bà ń pète ogun
Tó sì ń wá ọ̀nà àti forí lésùká sùn,
Ọ tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí rẹ kodoro…

Tó ba ń fìrù ejó seré
Sùgbọ̀n tó ǹ dúró pé kó kà á kéré,
Ọ tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí rẹ kodoro…

Tí wọ́n bá lù ẹ́ làlú tún lù
Sùgbọ́n sá tó sọ pé wọn ò lẹ́jọ́ láti jú,
Ọ tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí rẹ kodoro…

Tí o bá pọkẹrẹ mọ́ oníwà tútù ènìyàn
Bí olùsìn tó dàbí àródan Indian kan,
Ọ tọ́ sí ìgbàjú Màkàrọ́nù
Àtí ìkó lórí rẹ kodoro…

© Mutiu Olawuyi, 9 June 2021

Translated by: Taofeek Ọlálékan Ògúnpérí, 11 June 2021

About The Author

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Copyright © 2025 All rights reserved.